Bunny chow
Bunny chow jẹ́ oúnjẹ ilẹ̀ adúláwọ̀ tó gbajúmọ̀ ní apá Gúúsù Áfríkà, pàápàá jùlọ ní orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfríkà fúnrarẹ̀. Ó jẹ́ irúfẹ̀ oúnjẹ kan tí wọ́n maá n pèlò pẹ̀lú yíyọ ihò sáàrin búrédì láti lè da ọbẹ̀ ẹran tàbí ọbẹ̀ mìíràn sáàrin búrẹ́dì náà. Ó wọ́pọ̀ láàrin àwọn ìran índíàn tí wọ́n fi ìlu Dúrbàn ní orílẹ̀-èdè Gúúsù Áfríkà ṣebùgbé.