Fífún ọmọ lọ́mú
Fífún ọmọ lọ́mú jẹ́ ọ̀nà tí à ń gbà fún ọmọ ọwọ́ ní ọmú tó ń ti igbáàyà obìnrin wá.[1] Wàrà yìí le jẹ́ èyí tó wá láti ọmú tàbí èyí tí a fà sínú ike, tí a sì ń fún ọmọ mu. Àjọ tó ń rí sí ètò ìlera (WHO) dámọ̀ràn pé kí ọmọ ọmú bẹ̀rẹ̀ láàárín wákàtí àkọ́kọ́ tí a bí ọmọ sáyé, kí ó sì máa lọ bẹ́ẹ̀ títí tọ́mọ náà á fi dàgbà.[2] Àwọn àjọ ìlera, pẹ̀lú àjọ WHO, dámọ̀ràn pé ọmọ gbọ́dọ̀ mu ọmú nìkan fún odindin oṣù mẹ́fà gbáko láifi nǹkan kan kún.[3][4][5] Èyí túmọ sí pé wọn ò gbọdọ̀ ṣe àfikún oúnjẹ mìíràn tàbí ohun mímu mìíràn pẹlú ọmú náà, yàtọ̀ sí Vitamin D.[6] Àjọ WHO, dámọ̀ràn pé ọmọ gbọ́dọ̀ mu ọmú nìkan fún odindin oṣù mẹ́fà gbáko láifi nǹkan kan kún, lẹ́yìn tí wọ́n lè wá máa ṣàfíkún àwọn oúnjẹ mìíràn kún ọmú náà títí ọmọ náà á fi pé ọdún méjì. [3] [4] Nínú àwọn ọmọ mílíọ́nù 135 tí wọ́n ń bí lọ́dọọdún, 42% nínú wọn ló ń mu ọmú ní kété tí wọ́n bá bí wọn, 38% àwọn ìyá ló ń tèlé ìmòràn pé kí wọ́n máa fún ọmọ lọmú nìkan fún oṣù mẹ́fà àkọ́kọ́, 58% sì ló ń fún ọmọ lọ́mú títí wọ ọdún méjì àti jù bẹ́ẹ̀ lọ.[3]
Fífún ọmọ lọ́mú ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní sí ìyá àti ọmọ, ó sì máa ń fún ọmọ ní àwọn ohun tó ṣaláìní.[4] [7] [8] Fífún ọmọ lọ́mú máa ń ṣe ìdínkù sí àìsàn bí i ikó ìfe, àrù etí, ikú àìtọ́jọ́, àti ìgbẹ́ gbuuru ní orílẹ̀-èdè tó ti dàgbà àti èyí tó ṣì ń dàgbà lọ́wọ́.[9][10]
Àwọn ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Empty citation (help)
- ↑ Empty citation (help)
- ↑ 3.0 3.1 3.2 Empty citation (help)
- ↑ 4.0 4.1 4.2 Breastfeeding and the use of human milk. March 2012. http://pediatrics.aappublications.org/content/129/3/e827.long. Àṣìṣe ìtọ́kasí: Invalid
<ref>
tag; name "Johnston_2012" defined multiple times with different content - ↑ Optimal duration of exclusive breastfeeding. August 2012.
- ↑ "Breastfeeding".
- ↑ A summary of the Agency for Healthcare Research and Quality's evidence report on breastfeeding in developed countries. October 2009.
- ↑ Breastfeeding in the 21st century: epidemiology, mechanisms, and lifelong effect. January 2016.
- ↑ The Little Green Book of Breastfeeding Management for Physicians & Other Healthcare Providers. Madison, WI: The Institute for the Advancement of Breastfeeding and Lactation Education.
- ↑ Breastfeeding: A Guide for the Medical Profession. Elsevier Health Sciences. 1 January 2011.