Patrick Wilson
Patrick Joseph Wilson (tí a bí ní ọjọ́ kẹta oṣù keje ọdún 1973) jẹ́ òṣèré ọmọ orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà. Ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bi òṣèré ní ọdún 1995, nígbà tí ó ṣeré nínú Broadway musicals. Wọ́n yán mọ́ ara àwọn tí ó tó sí Tony Awards ní ẹ̀mejì fún ipa nínú eré The Full Monty (2000–2001) àti Oklahoma! (2002). Ó tún ṣeré nínú eré HBO tí àkọ́lé rẹ̀ jẹ́ Angels in America (2003), èyí tí ó mú kí wọ́n yán lé mejì mọ́ ara àwọn tí ó tó sí àmì ẹyẹ Golden Globe Award àti Primetime Emmy Award.
Patrick Wilson | |
---|---|
Wilson ní ọdún 2016 | |
Ọjọ́ìbí | 3 Oṣù Keje 1973 Norfolk, Virginia, U.S. |
Ẹ̀kọ́ | Carnegie Mellon University (BFA) |
Iṣẹ́ | Actor, director |
Ìgbà iṣẹ́ | 1995–present |
Olólùfẹ́ | Dagmara Domińczyk (m. 2005) |
Àwọn ọmọ | 2 |
Wilson farahàn nínú àwọn eré bi The Phantom of the Opera (2004), Hard Candy (2005), Little Children (2006), Watchmen (2009), àti The A-Team (2010). Ó gbajúmọ̀ si nígbà tí ó farahàn nínú eré Insidious film (2010–2023) àti gẹ́gẹ́ bi Ed Warren nínú eré The Conjuring universe (2013–títí di ìsinsìnyí).[1][2] Òun ló dárí eré Insidious: The Red Door (2023).
Àwọn Ìtọ́kasí
àtúnṣe- ↑ Oh, Sheryl (8 August 2018). "'Insidious' and 'The Conjuring' Star Patrick Wilson Finds His Next Horror Project". Film School Rejects.
- ↑ "In Praise of Patrick Wilson, "The Conjuring" Scream King". The New York Times. June 6, 2021. Retrieved June 8, 2021.