Ojúkò ìdìbò[1] jẹ́ ibi tí àjọ elétò ìdìbò pèsè kalẹ̀ fún àwọn olùdìbò tí wọ́n sì gbé àpótí ìdìbò sí kí ètò ìdìbò náà ó lè rọrùn. bí ó tilẹ̀ jẹ́ wípé ojúkò ìdìbò sábà ma ń túmọ̀ sí odidi ilé tabí gbọ̀ngàn kan tí àwọn olùdìbò yóò kórajọ sí tí wọn yóò sì tó lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti dìbò, amọ́, ojúkò ìdìbò gan gan ni ọ̀gangan ibi tí olùdìbò yóò ti dìbò fún olùdíje tí ó bá wùú.[2] Ojúkò yí sábà ma ń jẹ́ iyàrá kan tí àpótí ìbò wà tí olùdìbò kan ṣoṣo yóò wọ̀ lọ láti dìbò rẹ̀. [2] (or part of a room) where voters cast their votes. A polling place can contain one or more polling stations.[2] Nígbà tí ó jẹ́ wípé ètò ìdìbò gbogbo gbò sábà ma ń tó ọjọ́ kan sí ọjọ́ méjì tàbí kí ju bẹ́ẹ̀ lọ, ojúkò ìdìbò sábà ma ń jẹ́ ibùdó tí wọ́n ma ń ló fún nkan mìíràn gẹ́gẹ́ bí ilé ìjọsìn, pápá ìṣeré, ilé-ẹ̀kọ́, gbọ̀ngan ayẹyẹ, ilé-iṣẹ́ ìjọba ìbílẹ̀ ilé ìgbé àwọn ènìyàn tí ó lè gba ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ènìyàn lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Ibi tí ojúkò ìdìbò yí bá wà ni wọ́n ń pe ní wọ́ọ̀dù. Ojúkò ìdìbò yí ma ń jẹ́ ibi tí àwọn elétò ìdìbò àti elétò àbò tí wọn yóò ma tọ́ àwọn olùdìbò sọ́nà lórí ìgbésẹ̀ tí ó bá kàn tí àwọn elétò àbò yóò sì ma ṣàmójútó ìgbésẹ̀ ìdìbò kí ó lè já geere. Wọ́n ma ń ṣí Ojúkò ìdìbò yí sílẹ̀ fún àwọn àsìkò kọ̀ọ̀kan lọ́jọ́ ìdìbò fún ìgbésẹ̀ ìdìbò, wọn sì kí ń gba ẹlòmíràn láàyè láti súnmọ́ apótí ìdìbò yàtọ̀ sí ẹni tí ó fẹ́ dìbò àti àwọn olùdarí ètò ìdìbò pẹ̀lú àwọn elétò àbò tí wọ́n wà ní agbègbè náà.

Voting at a polling station in Ankara, 7 June 2015

Nínú ojúkò ìdìbò, ẹnu àpótí ìbò ni ni olùdìbò ti ma ń ní ànfaní láti lo ìwé ìdìbò láti fi yan olùdíje tí ó bá wú ní bòńkẹ́lẹ́ láì fi hàn fún ẹnikẹ́ni sínú àpótí ìbò. Lọ́pọ̀ ìgbà, wọ́n lè lo irinṣẹ́ kọ̀ọ̀kan láti fi ṣètò yí.

Ọpọ̀ ojúkò ìdìbò ni wọ́n ma ń jẹ́ fìdí hẹ, tí wọ́n sì ma ń ṣe atíbàbà síbẹ̀ fún ètò ìdìbò tí wọn yóò sì yọ àwọn ohun tí wọ́n ṣe síbẹ̀ lẹ́yìn ìdìbò.

Àpóti ìdìbò

àtúnṣe
 
New York polling place circa 1900, showing voting booths on the left.
 
Voting booths used for L’Ordre des Avocats de Paris (Paris Bar Association) 2007 election.

Àpótí ìdìbò ni ó jẹ́ ibi kékeré kan ti a ṣe lọ́jọ̀ fún olùdìbò kí ó lè dìbò rẹ̀ ní ìdákọ́nkọ́ láì sí ẹnìkan níbẹ̀. Ẹyọ ènìkan tí ó jẹ́ olùdìbò ni ó ma ń ní ànfàní láti wọ ibẹ̀ tàbí lo ibẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, ayà fi tí olùdìbò náà bá nílò ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ awọn elétò ìdìbò tó wà nítòsí. Pẹ́lú ìdagbàsókè tí ó ti dé bá ìmọ̀ ẹ̀rọ láyé òde òní, oríṣiríṣi ẹ̀rọ ìgbàládé ni wọ́n ti ń lò láti fi dìbò láyé òde òní. [3] [4][5]

Ìtàn rẹ̀

àtúnṣe

Ojúkò ìdìbò ninó jẹ́ ibintí a gbé kalẹ̀ fún ìkẹ́sẹjárí ètò ìbò níbi tí òndìbò yóò ti yan olùdíje tí ó bá wùú sípò pẹ̀lú alá títẹ̀ ìka. [6][7] Àmọ́ láyé òde òní ìdàgbà-sókè ti bá ètò ìdìbò yàtọ̀ sí bí ó ti wà laye atijọ́ ní nkan bí ẹgbàáléláàdọ́ta sẹ́yìn. Ojúkò ìdìbò ni wọ́n ti ma ń dìbò tí àwọn elétò ìdìbò yóò sì gbé ìwé mímó fun kí ó búra lórí ìbò rẹ̀ tí ó dì ṣáájú ka ìbò tí wọ́n bá di sétígbọ́ àwọn ènìyàn tí wọn yóò sì kéde olúborí nínú ètò náà. Wọ́n kọ́kọ́ ma ń ṣètò ìdìbò pẹ̀lú bí àwọn òndìbò yóò ṣe máa wá láti dárúkọ́ òndíje dupò tí wọ́n fẹ́ dìbò yàn. Wọ́n sábà ma ń lo ibi tí ó jẹ́ gbanbba fún irúfẹ́ ìgbésẹ̀ yí. Àmọ́, ìṣesí yí ti yí padà pẹ̀lú bí wọ́n ṣe ń lo ìwé ìdìbò tí òndìbò yóò sì tẹ̀ka tàbí ṣàfihàn olùdíje tí ó wùú sínú bébà pélébé tí wọ́n bá fun láti fi èrò rẹ̀ hàn.[8][8] Lílo bébà ìdìbò ati ìdìbò orí ẹ̀tọ ayélujára ni wọ́n ń sábà ń ṣamúlò laye òde òní.[8] Látàrí ọlàjú tuntun yí, wọ́n ní láti gbé ojúkò ìdìbò tí ó yanrantí kalẹ̀ kí apótí ìdìbò ó lè wà ní abẹ́ àbò tí péye. [8] Ìbò dídì ma ń wáyé nínú ilé tàbí ojúkò tí wọ́n ti gbé kalẹ̀ fún ètò náà. Àwọn òndìbò yóò lọ síbẹ̀ láti ṣe àyẹ̀wò nípa fífi ohun ìdánimọ̀ wọn hàn àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìdìbò gẹ́gẹ́ bí òfin ìdìbò.[8][9] Òndìbó tí ó bá ti yege nínú ayẹ̀wò yí ni yóò lánfàní àti dìbò nígbà tí àwọn elétò ìdìbò yóò fun ní ohun ìdìbò tí wọn yóò sì fi apótí ìdìbò hàn án kí ó lè lọ dìbò rẹ̀ fólùdíje tí ó wùú, tàbí kí ó fi ohun ìdìbò rẹ̀ dìbò lórí ẹ̀tọ ìdìbò ìgbàlódé. [8]

Ìjìnà ojúkò ìdìbò

àtúnṣe

Bí ojúkò ìdìbò bá ṣe jìnà sí sábà ma ń nípa tó lágbára lórí bí àwọn òndìbò yóò ṣe tà yáyá tà yàyà jáde láti lọ kópa ní ètò ìdìbò. Ìwádí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ wípé bí ìgbésẹ̀ ìdìbò bá ṣe le tó ni yóò mú kí àwọn òndìbò ó Sà sẹ́yìn láti kópa nínú ìbò dídì. [10] Bí ibi ojúkò ìbò bá ṣe jìnà sí ma ń jẹ́ ìkan gbòógì nínú ohun tí ó ma ń lé òndìbò sẹ́yìn. [10] Bí ojúkò ìdìbò kò bá jìnà sí ilé tàbí ibiṣẹ́ òndìbò, tí ìgbésẹ̀ ìdìbò náà sì rọrùn, yóò mú kí àwọn òndìbò ó tópọ̀ ó lè kópa nínú ètò ìdìbò.[11] Bí ojúkò ìdìbò bá ṣe jìnà sí dín olùkópa nínú ètò ìdìbò kù nígbà tí wọn kò bá lánfàní sí ètò ìrìnà tó yè kooro. [10].

Àwọn itọ́ka sí

àtúnṣe
  1. "polling place - definition of polling booth in English". Oxford Dictionaries. Archived from the original on October 26, 2013. Retrieved 29 October 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  2. 2.0 2.1 2.2 Handbook for polling station staff Archived 2016-10-05 at the Wayback Machine., Accessed 14 September 2014
  3. "Oxford Dictionaries". Archived from the original on October 27, 2014. Retrieved 19 October 2014.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)
  4. "Voting at a Polling Place". Australian Electoral Commission. Retrieved 28 May 2013. 
  5. "Voting in person". The Electoral Commission. Archived from the original on 2 June 2013. Retrieved 28 May 2013. 
  6. "Polling & Democracy: An Uneasy Relationship | On the Media". WNYC. 
  7. Lepore, Jill (November 9, 2015). "Are Polls Ruining Democracy?" – via www.newyorker.com. 
  8. 8.0 8.1 8.2 8.3 8.4 8.5 Douglas W. Jones (2003). "A Brief Illustrated History of Voting". Retrieved February 20, 2013. 
  9. "Voter Identification Requirements | Voter ID Laws". www.ncsl.org. Archived from the original on 2019-06-05. Retrieved 2019-06-07. 
  10. 10.0 10.1 10.2 Haspel, Moshe; Knotts, Gibbs (May 2005). Location, Location, Location: Precinct Placement and the Costs of Voting. 67. United States of America: Southern Political Science Association. pp. 560–573. 
  11. Tom Jacobs; Miller-McCune (August 19, 2010). "How Polling Places Can Affect Your Vote". Archived from the original on July 5, 2013. Retrieved February 20, 2013.  Unknown parameter |url-status= ignored (help)

Àṣìṣe ìtọ́kasí: <ref> tag with name "Matter" defined in <references> is not used in prior text.
Àṣìṣe ìtọ́kasí: <ref> tag with name "Voting Influence" defined in <references> is not used in prior text.
Àṣìṣe ìtọ́kasí: <ref> tag with name "Stanford" defined in <references> is not used in prior text.

Àṣìṣe ìtọ́kasí: <ref> tag with name "president" defined in <references> is not used in prior text.

Àwọn Ìtàkùn ìjásóde

àtúnṣe

Àdàkọ:Wiktionary

Àwọn itọ́ka sí

àtúnṣe

Àdàkọ:Authority control

  NODES
Association 2